IGBE AYE ISONIDIOMO EYIN (NBC DISCIPLE'S LIFESTYLE) Agbeyewo fun Osu Keje (July): LILEPA OHUN TI ARA *ORI ORO:* *IGBE-AYE KRISTIANI ATI ILEPA OHUN TI ARA.* *OSE KARUN-UN:* ỌJỌ́ ÀÌKÚ, ỌJỌ́ ỌGBỌN, OṢÙ KEJE, ỌDÚN 2023


 

IGBE AYE ISONIDIOMO EYIN

(NBC DISCIPLE'S LIFESTYLE) 

Agbeyewo fun Osu Keje (July):

LILEPA OHUN TI ARA

*ORI ORO:*

*IGBE-AYE KRISTIANI ATI ILEPA OHUN TI ARA.*

*OSE KARUN-UN:*

ỌJỌ́ ÀÌKÚ, ỌJỌ́ ỌGBỌN, OṢÙ KEJE, ỌDÚN 2023. 

*ORIN INU IWE:*

'Mo fi gbogbo Rę fun Jesu' - YBH 616


*BIBELI KIKA:*

Luku 12:13-31. 

*ILANA IKONI:*

*Ijiroro.*

*ABAJADE EKO ATI AWON ATOKA:*

 _Awon omo kilaasi yoo mo iha ti o ye ki Kristiani ko si ohun ti ara, won yoo si fi oye yii han nipa:_ 

i. Şişe atun gbeyewo ero Kristiani nipa ohun ti ara. 

ii. Şişe alaye lori bi Kristiani șe le je orisun ibukun fun awon miiran.

iii. Didaruko awọn ọna ti won le gba yago fun idanwo ti o le mu ki won maa lepa ohun ti ara.

*AKOKO IFARAKINRA:*

Je ki awon omo ipin meji jiroro lori awọn ọna ti won le gba ni oro ni ona ti Olorun.

*Oro Isipade Oludari Eko:*

Ile aye yii je eyi ti o nii șe pelu lilepa ohun ti aye ti o fi je pe awon eniyan n sare lati ni oro lonakona. Nnkan to n sele yii lodisi ife Olorun fun awa omo Re. Ife Olorun fun awa omo Re ni pe ki a gbe ninu opo sugbon kiişe de aaye ti a o fi wa so awon ohun ini ti ara di oriṣa akunlebo. Bi a ba ko lati yago fun iwa buburu yii, o le mu ki a şubu sinu idanwo lati tako ife Olorun fun igbe-aye wa. Wiwo Olorun ati diduro lori ife Re fun igbe-aye wa yoo mu ki a bori awon idanwo ti o le si oju wa si lilepa ohun ti ara nigba gbogbo. Gege bi omo-leyin Kristi, a gbodo dagba ki a si di iriju awon ohun ini ti Olorun lori ile aye.

AKOKO EKO/IFIKUNLUKUN*

*A. ERO KRISTIANI NIPA OHUN TI ARA*

Oye pe Olorun lo ni ohun gbogbo ati pe iriju lasan ni a je si awon ohun ini Rę gbodo maa se atona iha ti Kristiani kosi ohun ti ara. Ife wa fun Olorun gbodo tayo gbogbo awon ohun ti aye. Eleyii yoo mu ki a lo awon ohun amusagbara ti Olorun fifun wa pelu ogbon lati se anfaani fun ijoba Rę nile aye nibi yii. Gęgę bi Iwe Atumo Ede Merriam Webster șe wi, lilepa ohun ti ara "je agbara lati ri awon ohun ini tabi dukia ati igbadun ti aye bi ohun ti o ṣe pataki ti o si niye lori ju awon ohun ti emi lo." Niti Kristiani, ohun yoowu ti a ba gbega tabi ti o ję wa logun ju Olorun ati awon ohun ti emi lo ko tona rara. Ko si nnkan to buru ninu ki Kristiani ni dukia tabi awon ohun ini ki o si gbadun won; ṣugbọn ki ohun ti aye wa ję wa logun ju ife ti Olorun lo maa n mu ki eniyan so won di orisa akunlębo. A gbodo mo pe, ohun yoowu ti Olorun ba fifun eniyan ni a gbodo lo lati fi ogo fun Un ati lati fi bukun fun awọn miiran. Won ko wa fun iṣogo ti ara eni.

Kristiani ti ko ba kiyesara nipa lilepa awon ohun ti ara debi ti o ti fi wa gbe won ga ju awon ohun ti emi lo le şubu sinu pakute eşu. Idi ni pe, eșu le lo anfaani naa lati mu ki a lero pe ninu awon ohun ini tabi oro ni ona kan soso ti eniyan fi le ni itelorun nile aye. Nini awon ohun ini je etan debi pe o le mu awon oro Olorun to wa ninu aye eniyan kuro, ki o si so eni naa di alaimo (Maaku 4:19). Oro ti aye tabi ohun ini kii mu itelorun wa; Olorun nikan şoso lo le tan aini eniyan. Nitori naa, a gbodo ni itelorun pelu ohun yoowu ti a ni kiasi gbe Olorun ga ju ohun gbogbo ti a ni lọ.

*Akoko Ijiroro:* Gege bi oniwaasu ti wi ninu Iwe Oniwaasu 1:2, ki lo de ti a tokasi ilepa awon ohun ti ara bii 'asan'?

*B. AWA KRISTIANI BII ORISUN IBUKUN*

Bibeli kun lopolopo fun ogbon nipa ife Olorun fun iran eniyan ati ireti Re lati odo wa pe ki a san an ife Re fun wa fun awon miiran. Olorun kii şe nnkan laini idi.O n peșe fun aini wa ki a le ba aini awon miiran pade. Biba aini awọn miiran pade ni a le tumo si pe a je orisun ibukun fun won. Peteru Kinni 4:10 wi pe, "Bi olukuluku ti riebun gbà, bee ni kie máa se ipinfunni rẹ láàrin ara yín, bi iriju rere ti onírúurú oore-ofe Olorun." Gbogbo ibukun ti eniyan ri gba wa lati odo Olorun, a si gba awon ibukun yii nipa oore-ofe, kii șe nipa ise nitori Olorun lo n fi agbara lati ni orò funni. Nitori naa, awon ibukun naa je agbara, eyi ti o mu awa Kristiani je iriju. Gęgę bi Kristiani, ohun yoowu ki o je ipe tabi ise rę, o gbodo ri ara rę bii ibukun fun awọn miiran, nipa jije ibukun fun awon eniyan, rii bi ise-iranse. Ife Olorun ni pe ki o ni ipa rere lori iran eniyan. Eyi ni asiri oro. Luku 12:48 wi pe, "Nitori enikeni ti a fun ni pupo, lodo re ni a o gbé beere pupo..." Ni afikun, Bibeli tun so pe, "Ẹ fifun ni, a o si fifun yín; osuwon daradara, akìmole, ati amipo, akún-wosilę, ni a o won si àya yín" (Luku 6:38). Nitori naa, ninu ififunni ni eniyan ti n ri gba. Bi o ba șe fifunni si ni o oṣe ri gba si. Eyi ni aşiri didi alabukun fun.

*Akoko Ijiroro:* "Gbigbe igbe-aye fun ara eni ni gbigbe igbe-aye lati wa laaye; gbigbe igbe-aye fun awọn miiran je gbigbe igbe-aye ibukun.

*D. YIYAGO FUN AWON IDANWO TO LE YORISI LILEPA OHUN TI ARA*

Idanwo wa lopolopo, a si ni lati koju ija si won. Lopo igba, eșu maa n lo awon ohun ti ara lati fi ogboo-gbon di awa omo-leyin Kristi lowo ninu igbagbo. Lilepa ohun ti ara maa n wonu aye eniyan nigba ti eniyan ba je alaibikita lati mo awon arekereke eșu. Lopo igba ni a maa n ronu nipa awon ohun ti ara bii ounje, aso, ilegbe, moto ati bee bee lo, bi a ko ba si sora, lilepa wọn le di panpe ti o le tan onigbagbo wonu aye. Bakan naa, yoo si oju won kuro ni awon ete Olorun, yoo si so won di eru won. Awa onigbagbo ni lati kiyesara. Bi ilepa ohun ti ara se n gbiyanju lati mu akude ba igbe-aye ti ẹmi won, a n pe awon Kristiani lati fi owo ti o dara mu awọn ohun ti Olorun dipo awon ohun ti ara. Eniyan gbodo kiyesara ki o si maa gbadura ki o maa baa subu sinu idanwo ota. Awon nnkan wonyi yoo ṣe iranwo lati yago fun idanwo to le yorisi lilepa awon ohun ti ara: 

a. Maa kekoo ninu Oro Olorun nigba gbogbo ki o si maa șe awon nnkan ti o sọ. 

b. Maa gbadura nigba gbogbo ni ibamu pelu oro Olorun.

d. Maa fetisi awon eko ati iwaasu ti o wulo lati odo awon olusoaguntan ati awon olukoni ti o ni oruko rere nigba gbogbo. Maa figba gbogbo ranti ipadabo Jesu Kristi pelu erongba lati wa pelu Re. e.

e. Maa figba gbogbo ranti ete Olorun fun aye Re ki o si duro tabi ki o tęsiwaju ninu ete naa. Maşe ye kuro ninu igbagbo.

f. Gbekele Olorun fun ibukun Rẹ ki o si je ibukun fun awon miiran. Maa gboran si Olorun nigba gbogbo. Maṣe jẹ ki ohun miiran gba ipo Olorun ninu aye re. 

*Akoko Ijiroro:* Awon ona miiran wo ni onigbagbo le gba yago fun idanwo lati lepa awon ohun ti ara. 

*Oro Ipari Oludari Eko:* 

Olorun ti fi Oro Rẹ ti o ni imisi fun wa lati ṣawari otiito nipa awon ohun ti ara. A ko nilo ki a sese maa duro de enikeni lati so fun wa ki a to sawari awon otiito nipa bi o ṣe ye ki a gbe igbe-aye. Ki a le bo lowo agbara to romo lilepa awọn ohun ti ara, a gbodo mo-on-mo ka, ki a si kekoo ninu Iwe Mimo. Eleyii yoo ran wa lowo lati koju ija si oro ti o nii se pelu lilepa awon ohun ti ara. Ni afikun, e jẹ ki a si okan wa paya lati kekoo lati odo awon ara ti won je Kristiani ti won le ṣe iranlọwọ fun wa nigba ti a ba rii pe a fe subu sinu pakute eşu.

*Adura:* Gbadura pe Olorun yoo ba o soro lati lo awon ohun ini re ni ona ti Olorun.

*Işe-Şişe Leyin Eko:* Wa akoko lati ṣe iranlọwo fun enikan ti o mo ti o ti ṣubu sinu panpe ilepa ohun ti ara.

*ILANA FUN AWON OMO-LEYIN*

A dupe lowo Olorun fun awon eko ti a ti ko lori awon oniruuru oro to dale lilepa ohun ti ara. A ti fidi re mule pe Olorun lo ni aye ati orun ati ohun gbogbo ti o wa ninu rẹ ti o fi mo fadaka ati wura. Gege bi onigbagbo, a gbodo jawo ninu ijijadu lati ni oro ni onakona, nitori eleyii yoo kan mu ki a se si Olorun ni. Dipo bee, a gbodo gba Olorun laaye lati dari wa ninu ohun gbogbo ti a ba n şe. Nigba ti a ba fi Olorun se akoko ti a si sin In pelu gbogbo okan wa, yoo to ipa ona wa, yoo si bukun fun wa. Mo gbadura ki a ri iranlọwo lati bo lowo igbekun lilepa ohun ti ara gba ni oruko Jesu Kristi. Amin.

*Ojo Isinmi Yio Ba Wa Layo*

*E Tesiwaju lati Ma Se Ifarajin si Ise Ododo.*

Previous Post Next Post