ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Naijiria àti Oke Okun Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI OṢÙ KEJE - OṢÙ IKEJILA 2023 ÀKÒRÍ GBÒÒRÒ: NINI OYE IPILẸ JÍJẸ ÀPỌ́SÍTÉLÌ WA. ÉFÉSÙ 2:20 ÌSỌRI KÍNNÍ: ỌLỌ́RUN MẸTALỌKAN WA LATI RA WA PADA JULY 30, 2023 Ẹ̀KỌ́3 ÀKÒRÍ: ÌWÀ ÌṢÌNÀ/IDIBAJẸ PÁTÁPÁTÁ TÍ ÀBÙDÁ Ẹ̀DÁ ÈNÌYÀN

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI

Naijiria àti Oke Okun

Ẹ̀KỌ́ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI

OṢÙ KEJE - OṢÙ IKEJILA 2023

ÀKÒRÍ GBÒÒRÒ:

NINI OYE IPILẸ JÍJẸ ÀPỌ́SÍTÉLÌ WA.

ÉFÉSÙ 2:20

ÌSỌRI KÍNNÍ: ỌLỌ́RUN MẸTALỌKAN WA LATI RA WA PADA

JULY 30, 2023

Ẹ̀KỌ́3

ÀKÒRÍ: ÌWÀ ÌṢÌNÀ/IDIBAJẸ PÁTÁPÁTÁ TÍ ÀBÙDÁ Ẹ̀DÁ ÈNÌYÀN

AKỌSORI

Ọlọ́run si ri pé iwa búburú èniyàn di púpọ̀: ni ayé, àti pé gbogbo iro ọkan rẹ kiki ibi ni lojoojumọ (Genesisi 6:5).

Iwa ìṣìnà/idibajẹ ènìyàn ti bi iwa ika, ẹ̀rù, ibanujẹ ati gbogbo onírúurú iwa ibi to burú jáì lórí aye/araye. Ìràpadà nípasẹ̀ Kristi ni ọna àbáyọ kanṣoṣo!

 ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ 

Ìran ènìyàn ti o yẹ ki o gbé ìfẹ́ Ọlọ́run lárugẹ ti sọ iyi rẹ nu. Inu Ọlọ́run ko dun nígbà ti gbogbo ènìyàn ba di ènìyàn búburú bẹẹni ko si si ìyàtọ̀ kankan laarin àwọn ènìyàn lori ipilẹ iyi wọn mọ. Iwa búburú ènìyàn ti o di púpọ̀ ni a kó jọ pọ nínú ẹsẹ akọsori"..... àti gbogbo ìró ọkan rẹ kiki ibi ni lojoojumọ." Àwọn onigbagbọ ayé òde òní gbọ́dọ̀ kiyesara ki wọn o si gba ipenija láti gbé ìgbé ayé ti o tọ̀nà ki wọn o si maa dari ẹda eniyan pada sọ́dọ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bi Ọlọ́run ti fẹ́ (wo Mat. 5:13-16).

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ 

Mon. 24: Ọlọ́run Mọ Ènìyàn Po Yikaakiri (Job. 10:8) 

Tue. 25: Ọlọ́run Gba Ọna Ìyanu Yan Ènìyàn Sípò (Gen. 2:8-15)

Wed. 26: Ọlọ́run Kílọ Fún Ènìyàn (Gen. 2:16-17)

Thur. 27: Iyan Aìwà-bí-Ọlọ́run Koba Ènìyàn (Gen. 3:4-7) 

Fri. 28: Iwa Aìwà-bí-Ọlọ́run Ti Ènìyàn Jáde Kúrò Nínú Ìtura/Ayọ (Gen. 3:22-24)

Sat. 29: Igbọjẹgẹ/Ifaaye Gba Ẹtan Èṣù Mu Kí Ẹda Ènìyàn Ṣina/Dibajẹ Pátápátá (Rom. 3:23)

 ÀWỌN ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN 

1. Ko si ẹni ti o ṣáko lọ kúrò nínú odiwọn mímọ Ọlọ́run ki o tún wa ni iduroore síbẹ̀. Ẹsẹ máa n ba aye ẹnikẹni ti o ba fi aaye gba a jẹ ni.

2. Ẹṣẹ a maa tẹ ènìyàn ri; máṣe jẹ ki o tẹ ọ ri!

 ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́: Romu 3:23.

4. ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA:

ILEPA: Láti mẹ́nuba irẹsilẹ ènìyàn láti ipasẹ ẹṣẹ Ádámù àti Éfà. 

ÀWỌN ERONGBA: Ni ìparí ẹkọ yii, anreti pé ki àwọn akẹ́kọ̀ọ́ o le: 

i. sọ bí àṣe da ènìyàn àti erongba ìwàláàyè rẹ; 

ii. ṣàlàyé àwọn igbese ti o fa idibajẹ ènìyàn, àti láti 

iii. ṣàlàyé àwọn àbájáde idibajẹ/ìṣubú náà. 

IFAARA

ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: GENESISI 1:26-31; 3:1 SWJ; 6:5; JOBU 15:16; ORIN DÁFÍDÌ 139:13-16; ROMU 3:23

Ọlọ́run ti jẹ olotitọ si wa nínú àwọn ẹ̀kọ́ méjì to kọja lọ gẹ́gẹ́ bi O ti mú wa la ẹ̀kọ́ ìlànà àkókò ti ìjọ wa yii kọjá 'Ìṣọkan ti Ọlọ́run (Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ) ati MẸTALỌKAN àwọn Ẹni ti n bẹ nínú Rẹ'. A ṣe agbekalẹ òtítọ́ yii, Ìṣọ̀kan Ọlọ́run MẸTALỌKAN ati ẹ̀kọ́ inu Bíbélì nípa mẹtalọkan. Nitòótọ́, ọkànṣoṣo ni Ọlọ́run wa, síbẹ̀ nínú Ẹni mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. 

Ẹ̀kọ́ kẹta ni yii nínú ọwọ yii. O dálori 'Iwa ìṣìnà/idibajẹ pátápátá ti àbùdá ẹda ènìyàn, idi pàtàki fún ìrònúpìwàdà àti atunbi ati ìparun ayérayé ti yóò gbẹyin alaironupiwada. Ìṣìnà pátápátá ni ipo ìṣubú iran ènìyàn nítorí abajade ìṣubú Ádámù nínú ọgba Édẹ́nì ni ọna ti o fi jẹ pé ohun gbogbo nípa ènìyàn ni o ti dibajẹ nípa ẹṣẹ, ti o si bẹ̀rẹ̀ si ni pín nínú àwọn àbájáde to tinú ẹṣẹ naa wa. Ijẹniya náà nínú Gen. 3 tí ó wa sórí ẹda ọkùnrin àti obìnrin, àti àwọn ẹranko àti àwọn ohun ọ̀gbìn jẹ ẹ̀rí pé àwọn ìran lẹyin Ádámù ti dibajẹ titi di òní yii nípasẹ̀ ìṣubú rẹ. Ọlọ́run n fẹ́ ki a kó àwọn ẹ̀kọ́ kan nínú òtítọ́ yii gẹ́gẹ́ bi a ti n ni òye daradara nípa ẹ̀kọ́ ìlànà wá kejì. 

KÓKÓ Ẹ̀KỌ́ 

I. ÈNÌYÀN: A DA A TIYANUTIYANU ÀTI TẸRURẸRÙ

II. ÈNÌYÀN DI ẸNI ÌṢÌNÀ (IDIBAJẸ) PÁTÁPÁTÁ 

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́ 

I. ÈNÌYÀN: A DA A TIYANUTIYANU ÀTI TẸRURẸRÙ (Gen. 1:26-31;O.D. 139:13-16) Emi o yin O; nitori tẹrutẹru ati tiyanu-tiyanu ni a dà mi: iyanu ni iṣẹ́ Rẹ; eyini ni ọkan mi si mo dájúdájú (O.D. 139:14). 

a) O.D. 139:13-15: Pẹ̀lú ìtọ́kasi ami àpẹrẹ ni Dáfídì fi rántí ìṣẹ́ ìṣẹ̀dá ènìyàn latọrunwa, ti a da lọ́nà ìyanu, ìjìnlẹ̀ àti pẹ̀lú ọgbọ́n. Jobu pẹ̀lú jẹwọ eyi bákan naa (Job. 10:8).

b) Gen. 1:26-31 ṣe àkọsílẹ̀ bi Ọlọ́run ṣe pe igbimọ Mẹtalọkan (ẹsẹ 26), ti O ṣẹda ènìyàn ni àwòrán àti iri Rẹ láti inú erupẹ ilẹ̀ wa (ẹsẹ 26,27), ti O si sure lori ènìyàn pẹ̀lú àṣẹ àkóso ti oun ko yẹ fun, lórí àwọn ẹ̀dá ìyókù (ẹsẹ 28-30).

d) Ẹsẹ 31: Bi Ọlọ́run ba wi pé ohun gbogbo dára lọpọlọpọ, a jẹ wi pé ìṣẹ̀dá ènìyàn jẹ pípé nitootọ-tẹru-tẹru àti tiyanu-tiyanu ni a da mi' (O. D. 139:14). 

e) O. D 139:16: Ọlọ́run kò ṣẹda ènìyàn láìní erongba. O ni gbogbo nnkan nípa ènìyàn, ni pàtó, ti O ti ko sínú ìwé Rẹ, ṣáájú ayérayé àti ọjọ́ ti a fi fún un. Irú Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n àti eleto wo ni yii! 

e) Ọlọ́run dá ènìyàn fún ògo Rẹ, láti maa ni idapọ pẹ̀lú Rẹ ati fún isin Rẹ (wo Efe. 2:10). Dáfídì mọ eyi, o si ṣèlérí láti maa yin Ọlọ́run nígbà gbogbo (O.D. 139:14). Ìwọ pẹ̀lú gbọ́dọ̀ faraji fún èyí. 

f. Lékè gbogbo rẹ, eniyan ti a da tẹrutẹru àti tiyanutiyanu ni a da fun iyin Rẹ àti ìdùnnú Rẹ (Ifih.4:11). 

II. ÈNÌYÀN DI ẸNI ÌṢÌNÀ (IDIBAJẸ) PÁTÁPÁTÁ (Gen. 3:1 swj; 6:5; Job 15:16; Rom. 3:23).

Ọlọ́run si ri pé ìwà búburú ènìyàn di púpọ̀ ni ayé, àti pé gbogbo iro ọkàn rẹ kiki ibini lojoojumọ (Gen. 6:5).

a) Gen. 6:5 Ọlọ́run Olumọ hun gbogbo ri ipo ọkan ènìyàn kedere - iwa búburú ènìyàn papọju, gbogbo èrò rẹ kiki ibi ni (wo 8:21), lékè gbogbo rẹ o kún fún ẹ̀tàn (Jer. 17:9). Kin ni idi? Bawo?

b) 3:1 swj: Ẹda ènìyàn ti n bẹ nínú Ádámù gbọ́ràn si ìdánwò (ẹ̀tàn) satani, eyi si mu ìṣìnà/idibajẹ àti ìdálẹ́bi wa sórí ẹda ènìyàn. O jẹ ọrọ ìyàn (ìpinnu ṣíṣe) (2:15-17; wo Deut. 30:11).

d) Ọlọ́run n reti pe ki ènìyàn maa dúpẹ́ títí ayérayé fún ojurere ti o ga julọ ti ko yẹ fún ti O fun un latọrun wa (wo O.D. 139:14). Dípò bẹẹ àti ni èyí to báni-nínújẹ julọ, o ṣiyèméjì ìṣotitọ Ọlọ́run sí ìpalára ara rẹ. Wayi o, o di ẹni to dibajẹ pátápátá (Jer. 17:9), ti a si da a lẹ́bi ikú (Gen. 3:19; Rom. 3:23) 

e) Job. 15:16: Láti ṣafihan bi ènìyàn ṣe fẹ́ràn ẹṣẹ to, bi o ṣe ìjìnlẹ̀ tó nínú aisedeede ni a fi wé mimu omi. O nira sọ̀rọ̀ lọpọlọpọ fún ènìyàn ẹlẹ́ran-ara láti ṣe laidẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bi omi ṣe jẹ́ dandan fún ìwàláàyè (wo. O.D. 51:5) 

e) Rom. 3:23: Awegbolohun yii. "gbogbo ènìyàn lo saa tiṣẹ"n fidi iwa ẹṣẹ ènìyàn jákèjádò ayé múlẹ̀. Iwa ìṣìnà yii mu ki ènìyàn kùnà nínú odiwọn Ogo Ọlọ́run, idi ni yii ti o fi nílò ìrònúpìwàdà 

f. Atipe láìsí ìrònúpìwàdà, ìdáríjì yóò di ohun ti o nira ti ko ni laari.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TI A RI KỌ 

1. Ọlọ́run da ènìyàn lọ́nà ìyanu àti lọ́nà àrà. Ka ni ènìyàn ò ṣiwahu ni, ẹ finuro iru ayọ̀ àti àlàáfíà òun ìbùkún ti a ba maa gbádùn. Irú ìrora wo ni yii! 

2. Ènìyàn di ẹni idibajẹ nítorí ìwà àìgbọràn àti otp rẹ. Síbẹ̀, ìrètí ṣi wa fún ènìyàn nítorí Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run 

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ 

1. Ṣàpèjúwe bi ibapade rẹ ṣe mú ọ yàtọ̀ si àwọn ẹ̀dá miran. Kin ni ipa Ọlọ́run nínú eyi?

2. Ádámù àkọ́kọ́/kinni dá gbogbo ènìyàn lẹbi. Ẹjiroro

 ÀWỌN ÌDÁHÙN TI A DABAA FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ 

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ 1:

* Igbimọ mẹtalọkan kópa nínú ìṣẹ̀dá ènìyàn (Gen.1:26-37) A dá ènìyàn ni àwòrán ati iri Ọlọ́run, láti inú erupẹ ilẹ̀ (Gen. 1:26)

* Ọlọ́run fún rárá Rẹ ṣíṣẹ lori ìṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú sísun mọ ọn, o si mi sii lati di alaaye ọkàn (Gen. 2:7).

* A fi ji jọba lori àwọn ohun ti a da ke ènìyàn (Gen. 1:28-30) A da ènìyàn fún ògo Ọlọ́run, fún ìjọsìn àti ìṣẹ́ (Efe.2:10; Efih.4:11).

 Ojúṣe Ọlọ́run 

O fẹ ẹ, O ṣe to rẹ O mu sẹ bẹẹni O si n ṣe àbójútó rẹ (O.D.22:28).

IDAHUN SI ÌBÉÈRÈ 2:

Gbogbo ìran ènìyàn, nípasẹ̀ Ádámù, mọ ọ mọ yọnda ara rẹ fún ìdánwò sátánì èyí ti o ìyọrísí ìṣubú ati idajọ gbogbo ènìyàn (Gen. 3:1 swj; Mat. 1:21; Romu 3:23;5:12-21).

ÀMÚLÒ FÚN ÌGBÉ AYÉ ẸNI 

Lẹyin ti a ti da a tẹrutẹru àti tiyanutiyanu, ti a si fi jọba lórí ìṣẹ̀dá yókù , ènìyàn ṣàìgbọràn si Ọlọ́run o si gba ẹbi. Ẹwà ati jijọba ènìyàn ni a gba lọwọ rẹ nítorí àìgbọràn rẹ si Ọlọ́run. Àìgbọràn àti ẹṣẹ rẹ wa di ẹda/abuda ara àwọn ìran ti wọn wá lẹ́yìn rẹ. Ipo ti ènìyàn wa ni yii lẹ́yìn ìṣubú. Inú Kristi nìkan ni a ti ṣe ilaja pẹ̀lú Ọlọ́run ti a si di tuntun. Gbogbo ènìyàn ti o ba ìrònúpìwàdà ti o si kọ ẹṣẹ rẹ sílẹ̀ ti osi gba igbala yóò di atunbi ati àtúnda nínú Kristi Jésù. Maa fẹ: wa sọ́dọ̀ Jésù lonii.

 IGUNLẸ.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ti O ran wa lọ́wọ́ láti mú ẹ̀kọ́ yii wa si igunlẹ. Inú wa dùn nítorí ti a mọ pé ènìyàn ko ni tẹsiwaju nínú idibajẹ yii mọ nítorí Jésù ti wá Alati tun ohun gbogbo ṣe. A rọ ọ láti gba Jésù ni Olúwa àti Olùgbàlà rẹ lonii.

ÀKÍYÈSÍ

Previous Post Next Post