ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Naijiria àti Oke Okun OMI IYE NAA, (January- December, 2023) Ojọ AIKU (Sunday) July 30, 2023. ÀKÒRÍ: ẸGBẸ AWỌN AṢIPẸ

 


ÀKÒRÍ: ẸGBẸ AWỌN AṢIPẸ

AKỌSORI:

   Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe (ÌWÉ ÒWE 13:20)

KA:DANIẸLI 2:14-19

[14]. Nigbana ni Danieli fi ìmọ ati ọgbọ́n dahùn w fun Arioku, ti iṣe balogun ẹṣọ ọba, ẹniti nlọ pa awọn amoye Babeli. 

[15]. O dahùn o si wi fun Arioku, balogun ọba pe, Ẽṣe ti aṣẹ fi yá kánkán lati ọdọ ọba wá bẹ̃? Nigbana ni Arioku fi nkan na hàn fun Danieli. 

[16]. Nigbana ni Danieli wọle lọ, o si bère lọwọ ọba pe, ki o fi akokò fun on, o si wipe, on o fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba. 

[17]. Nigbana ni Danieli lọ si ile rẹ̀, o si fi nkan na hàn fun Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀. 

[18]. Pe, ki nwọn ki o bère ãnu lọwọ Ọlọrun, Oluwa ọrun, nitori aṣiri yi: ki Danieli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ má ba ṣegbe pẹlu awọn ọlọgbọ́n Babeli iyokù, ti o wà ni Babeli. 

[19. ]Nigbana ni a fi aṣiri na hàn fun Danieli ni iran li oru, Danieli si fi ibukún fun Ọlọrun, Oluwa ọrun. 

ITUPALẸ

      Daniẹli ni awọn ọrẹ ti wọn ṣetan lati koju ohun gbogbo pẹlu adura. Awọn ọrẹ mẹta ti wọn jẹ ara Heberu yii mọ YAHWEH daradara, bẹẹni wọn si mọ ọna Rẹ. Awọn wo ni ọrẹ rẹ? Iru ọrẹ ti o ni ni yoo sọ iru eniyan ti o jẹ (Owe 27:17). Nigba ti ọba fẹ pa awọn aworawọ, alupayida ati awọn oṣo rẹ nitori ti wọn ko le tumọ ala rẹ, Daniẹli ati awọn ọrẹ rẹ gba wọn nitori ti wọn mọ Ọlọrun wọn, nipa eyi wọn ṣiṣẹ gidigidi ( Dan.11:32b). Lọna iyanu....a fi aṣiri naa han ( 2:19). Kin ni idi? Awọn ọrẹ kan fohun ṣọkan ninu adura ododo, ti n ṣiṣẹ agbara ( Jak. 5:16; wo Mat. 18:18-20).

          O dabi ẹni pe Ijọ ti sọ agbara yii nu. Bibẹẹ kọ, kin ni idi ti ọta fi n dẹruba a nigba ti o ni agbara Ọlọrun ti ko ṣe e da duro? Ni atetekọṣe, ti ọmọ Ijọ kankan ba ni iṣoro, awọn ẹgbẹ aṣipẹ tabi awọn ti wọn jọ n gbadura yoo maa gbadura fun wọn. Nibo ni aṣa yii salọ si ( Dan.2:17-19; Jak. 5:16)? Awọn ọrẹ Daniẹli ṣetan fun adura nigba gbogbo. Wọn jẹ ọrẹ rẹ ati ẹgbẹ ajumọgbadura rẹ. Ti o ba wa ninu iṣoro, njẹ o ni awọn ọrẹ ti wọn le gbadura fun ọ tabi fun ọ ni imọran? Ti ko ba si, o ko ni ọrẹ, ki o mọ eyi. " Ọrẹ nigba iṣoro ni ọrẹ tootọ" gẹgẹ bi oni ti jẹ ayajọ ọjọ Ibadọrẹ ni agbaye. " Eniyan rere meji san ju ẹnikan lọ" ( Oniw. 4:9-12). Tani ọrẹ rẹ ti ẹ jọ n gbadura? Ṣe ọrẹ rẹ ni tabi ọta rẹ? Ohun ti o lewu ni fun ọ lati ni ọta rẹ bii ẹni ti ẹ jọ n gbadura, nitori niti ara nikan ni ẹ o jọ maa ṣọkan ti ẹ ba ti ri ara yin lojukooju, ṣugbọn ki iṣe ninu ẹmi. Leke gbogbo rẹ, fi Jesu ṣe ọrẹ rẹ akọkọ, Ẹni ti o jẹ olootọ ati olododo. Orẹ wo la ni bii Jesu!       

Awọn Koko Adura

1. Dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o fẹ 

      ọ, ti o si fi ọ ṣe ọrẹ Rẹ.

2. Baba Oluwa, ran mi lọwọ lati pa gbogbo ipongbẹ aiwa-bi-Ọlọrun fun ẹgbẹ buburu ti n ba iwa rere jẹ, run.

3. Oluwa, da Ẹmi iṣipẹ, isọkan ati ifẹ ara pada sinu ijọ Rẹ.

Orin Ti A Dabaa, I.O. CAC: 890

ẸẸDẸGBẸRUN O DIN MẸWA

             10.9.10.9. & Ref.

Jesu sọ fun wọn pe.....emi wa pẹlu yin nigbagbogbo, titi o fi de opin aye. Mat. 28:20.

1. Ore bi Jesu kosi laye yi, 

   Oun nikan l'ore otito, 

   Ore aye yi y'o fi wa sile; 

   Sugbon Jesu ko je gbagbe wa. 

Ah! ko je gbagbe wa;

Ah! ko je gbagbe wa;

Sugbon Jesu ko je gbagbe wa. 

2. Akoko nkoja lo laifota pe; 

   A f'ojo kan sunmole wa si; 

   Onidajo mbo, gongo yi o so; 

   Awawi kan kosi l'ojo na. 

3. Duro d'Oluwa, ma siyemeji 

   Ohunkohun t'o wu ko le de; 

   'Gbat' o ro p'o pin 'ranwo Re y'o de; 

   Eni 'yanu l'Oba Oluwa. 

Amin.

Afikun Ibi Kika Fun Oni:

Owe 14-16.

Previous Post Next Post