YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER'S MANUAL Ẹ̀KỌ́ KEJÌDÍNLÁÀDỌ́TA (48) ỌJỌ́ ỌGBỌ̀NJỌ́, OSU KEJE, ỌDÚN 2023 - AKORI: ÌWẸ̀NÚMỌ́ ARA ẸNI

 


YORUBA RCCG SUNDAY SCHOOL TEACHER'S MANUAL

Ẹ̀KỌ́ KEJÌDÍNLÁÀDỌ́TA (48)

ỌJỌ́ ỌGBỌ̀NJỌ́, OSU KEJE, ỌDÚN 2023 - AKORI: ÌWẸ̀NÚMỌ́ ARA ẸNI

À̀DÚRÀ ÌBẸ̀RẸ̀: Baba Alágbára, jọ̀wọ́ kọ́ ni bí mo ṣe le wẹ ara mi mọ́ lójoojúmọ́ fún ìlò rẹ ní orúkọ Jesu.

ÌMỌ̀ ÀTẸ̀HÌNWÁ: Kí olùkọ́ gba ìgbákejì láàyè láti ṣe àtúnyẹ̀wọ̀ iṣẹ́ ọ̀ṣẹ̀ tí ó lọ.


Ẹ̀KỌ́ TÒNÍ

1. ÌBẸ̀RẸ̀

(I) BÍBÉLÌ KÍKÀ: Heberu 10:19-23.

19. Ará, njẹ bi a ti ni igboiya lati wọ̀ inu ibi mimọ́ nipasẹ ẹ̀jẹ Jesu, 

20. Nipa ọ̀na titun ati ãye, ti o yà si mimọ́ fun wa, ati lati kọja aṣọ ikele nì, eyini ni, ara rẹ̀;

21. Ati bi a ti ni alufa giga lori ile Ọlọrun;

22. Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù.

23. Ẹ jẹ ki a dì ijẹwọ ireti wa mu ṣinṣin li aiṣiyemeji; (nitoripe olõtọ li ẹniti o ṣe ileri;)


(II) ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: ”Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ni ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a ma sọ ìwà mímọ́ di pípé ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run” 2 Kọr.7:1.


(III) ÌFÁÀRÁ: Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ mímọ́ ní òde àti ní inú. (Sek.3:4). Ó fẹ́ràn àwọn tí ọkan àti ìgbésí ayé wọn jẹ́ pípé síi ó sì ti se ìpèsè fún ìwẹ̀númọ́ wọn ní gbogbo ọ̀nà. (Heb.10:23).

Nínú Orin Dafidi 51:7, Dafidi gbàdúrà fún ìwẹ̀númọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àwa pẹ̀lú ní ojúse pàtàkì láti ṣe nínú ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí náà, a ní láti yẹ́ ọ̀rọ̀ yíyẹ ara ẹni wò fínní-fínní.


ÀKỌSÍLẸ̀ OLÙKỌ́

(I) ÌLÉPA Ẹ̀KỌ́: Láti ṣe àṣàrò lórí ìtúmọ̀ àti ọna ìgbàṣe ìwẹ̀nùmọ́-ara-ẹni.


(II) ÈRÒǸGBÀ Ẹ̀KỌ́: Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí, Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò lè:

a. Ní òye ohun tí à ǹ pè ní iwẹ̀númọ́-ara-ẹni. 

b. Ni òye bí a tí ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́-ara-ẹni


(III) ÈTÒ KÍKỌ́NI: Láti ní ìmúṣẹ ìlépa tí a kọ sókè yìí, Ki olùkọ́:

a. Gba akẹ́kọ̀ọ́ láti gba àdúrà ìbẹ̀rẹ̀, tọ́ àwọn akẹ́kòó láti ka àkósórí, ẹsẹ Bíbèlì àti láti ṣe àtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ ọ̀sè tó kọjá. 

b. Gba ìgbákejì olùkọ́ láàyè láti se àtúnyẹ̀wò isẹ́ ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá, se àkóso kíláàsì, kí wọ́n sì se ìránwọ́ láti máàkì iṣẹ àṣẹtiléwá. 

d. Ṣàlàyé ẹ̀kọ́,sọ ní sókí, ṣe ìkádìí, ìgbéléwọ̀n ẹ̀kọ́, kí o sì fún wọn ní iṣẹ́ àmúrelé.


(IV) ÀTÚNYẸ̀WÒ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Heberu 10:19-23.

-Kí olùkọ tọ́ka sí àǹfààní márùn-ún tí ikú Jesu ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ (tàbí ìran ènìyàn) gẹ́gẹ́ bí a ti rí nínú àwọn ibi kíkà òkè yìí.

i. --------------------------

ii. -------------------------

iii. -------------------------

iv. -------------------------

v. --------------------------


(V) ỌGBỌ́N ÌKỌ́NI: Kí olùkọ́ lo ọgbọ́n ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìjíròró fún ẹ̀kọ́ náà.


(VI) LÍLÒ ÀKÓKÒ: Kí olùkọ́ pín àkókò ìkọ́ni fún ìlànà ẹ̀kọ́ méjèèjì kí ó pín àkókò náà dọ́gba.


2. ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́ 1: KÍNI ÌWẸ̀NÚMỌ́ ARA ẸNI?

A. ÌTÚMỌ̀ ÌWẸ̀NÙMỌ́ ARA ẸNI:

i. Ó jẹ́ ìgbìyànjú àmọ̀ọ́mọ̀ fínúfíndọ̀ ṣe ènìyàn láti wẹ ara rẹ̀ mọ kuro nínu gbogbo èérí- (2 Kọr. 7:1).

ii. Ó jẹ́ ìpinnu àtọkànwá láti di mímọ́ àti ìtẹ́wọ́gbà sí Ọlọ́run nípasẹ ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí mímọ́.

iii. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ tó lágbára ní ti èérí ayé ènìyàn bí a ti fihàn látọwọ ẹ̀mí mímọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Isa 6:5).

iv. Ó jẹ́ ìsọ ọkan ẹni di ọ̀tun-(Rom 12:2).

v. Ó jẹ́ gbígbé gbogbo ìwà búburú sọnù. Isa 1:16.

vi. Ó jẹ́ ìpinnu tí ẹ̀mí mímọ́ tì lẹ́yìn láti má fi ààye gba èrò àìmọ̀ àti ìwà búburú láti ráàyè lọ́kàn an wa-Jer. 4:14.

viii. O jẹ bíbọ́ ògbólògbó ọkùnrin nì sílẹ̀ àti ìṣe rẹ. Efe 4:22, Kol.3:9.

ix. Ó jẹ́ gbígbe ọkùnrin titun un ni wọ̀ àti òdodo rẹ ní àwòrán Kristi. Efe 4:24.


ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ ÌWẸ̀NÙMỌ ARA ẸNI

i. Ìwẹ̀nùmọ́ ara ẹni a máa bu ọlá fún onígbàgbọ́ ati ohun èlò tó wúlò lọ́wọ́ Ọlọ́run- 2Tim 2:21.

ii. O máa ń mu kí ireti onígbàgbọ́ nínú ayérayé tẹ̀síwájú pẹ̀lú Jesu nítorí àwọn tí yóò jọba pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. 1Joh. 3:3.

iii. Ìwẹ̀númọ́ ara ẹni máa ń múra wa láti jẹ́ aláìlábùkù níwájú Ọlọ́run-Orin Daf. 24 4-6, Heb 10:22.

iv. O máa ń mu ìdáhùnsí àdúrà yá tàbí ru ú sókè-Orin Daf. 24:5.


IṢẸ́ ṢÍṢE NÍ KÍLÁÀSI KÍNNÍ: Kí kíláàsì jíròrò lórí àwọn ohun ẹ̀gbin tí ó le sọ Kristiẹni di eléèrí.


ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́ 2: BÁWO NI ÈNÌYÀN ṢE LE WẸ ARA RẸ̀

A. A wẹ wa nípasẹ̀ tita ẹ̀jẹ̀ Jesu sílẹ̀, Heb. 9:14, 22.


B. Ṣùgbọ́n láti wẹ ara wa mọ́, A gbọ́dọ:

i. Gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ ọlọ́run pátápátá.-Orin Daf. 119:9.

ii. Pa gbogbo ẹ̀sẹ̀ tì àti ìdíwọ́ tí o le kó èérí bá ìwà mímọ́ wa tàbí tí ó le bàá jẹ́.- Heb 12:1.

iii. Yàgò/takéte sí ohun tó jọ ibi - 1 Tẹsa 5:22.

iv. Gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàyè láti wẹ̀ wa mọ kí ó sì tọ́ wa sọ́nà bí ó tilẹ̀ mú ìrora dáni-Efe 5:26, Esek 36:25, Heb. 10:22.

v. Má fi ààyè sílẹ̀ fún ẹran ara láti tì ọ́ sínú ẹ̀sẹ̀-Rom 8:13, Kol 3:3-5, 8-9.

vi. Fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún Ẹ̀mí mímọ́ láti, gbàsàkóso èrò àti iṣe wa kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ pátápátá-Jak. 4:8.


IṢẸ́ ṢÍṢE NÍ KÍLÁÀSI KEJÌ: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì jíròrò àbajáde ìgbìyànjú ara ẹni fún ìwẹ̀númọ́-ara-ẹni láìni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ nínú.


(3) ÌSỌNÍṢÓKÍ: ìwẹ̀númọ́-ara-ẹni jẹ́ ipò láti wúlò fún Ọlọ́run.


(4) ÌKÁDÌÍ: Bí o ba wà nínú Kristi nítòótọ́ tí ẹ̀mí rẹ̀ sì wa nínú rẹ, ìwẹ́nùmọ ti ara kì yóò jẹ́ ohun tí ó ṣòro.

(5) ÌGBÉLÈWỌ̀N: Sàpèjúwe ìwẹ̀númọ́ ara-ẹni àti àwọn ohun tí àti ń béèrè fún.


(6) ÀDÚRÀ ÌPARÍ: Kí àwọn akékọ̀ọ́ gba àdúrà fún ìwẹ̀nùmọ́ gidi láti wúlò fún ìlò Olúwa.


(7) ISẸ́ ÀSETILÉWÁ: Kọ ohun màrùn ún tí ó sọ ọmọ Ọlọ́run di aláìmọ́ sílẹ̀ (2x5=Máàkì Mẹ́wàá).

Previous Post Next Post