ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Naijiria àti Oke Okun OMI IYE NAA, (January- December, 2023) Òjọ ẸTI(Friday) August 4, 2023. ÀKÒRÍ: MAṢE FỌNNU NIPA ỌJỌ ỌLA(11).

 ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI 

Naijiria àti Oke Okun 

OMI IYE NAA, (January- December, 2023)

Òjọ ẸTI(Friday) August 4, 2023.

ÀKÒRÍ: 

MAṢE FỌNNU NIPA ỌJỌ ỌLA(11).


AKOSORI:

     Ete pupọ li o wà li aiya enia; ṣugbọn ìgbimọ Oluwa, eyini ni yio duro (ÌWÉ ÒWE 19:21).

KA:

LUKU 12:16-20


[16]. O si pa owe kan fun wọn, wipe, Ilẹ ọkunrin kan ọlọrọ̀ so eso ọ̀pọlọpọ: 


[17]. O si rò ninu ara rẹ̀, wipe, Emi o ti ṣe, nitoriti emi kò ni ibiti emi o gbé kó eso mi jọ si? 


[18]. O si wipe, Eyi li emi o ṣe: emi o wó aká mi palẹ, emi o si kọ́ eyi ti o tobi; nibẹ̀ li emi o gbé tò gbogbo eso ati ọrọ̀ mi jọ si. 


[19]. Emi o si wi fun ọkàn mi pe, Ọkàn, iwọ li ọrọ̀ pipọ ti a tò jọ fun ọ̀pọ ọdún; simi mã jẹ, mã mu, mã yọ̀. 


[20]. Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ? 


ITUPALẸ


       Ẹnu ipe kan nipa ijanba lasan, atẹjiṣẹ nipa ikọ́ kan ti o yi si akọ ibà, inu rirun, ile-iṣẹ ti o deede gbiná, tabi ibi igbafẹ kan ti awọn agbebọn ṣe akọlu si abbl, le ba eto ọjọ kan jẹ bi ko ba jẹ titi aye! Ile aye runiju ju ki a ma maa fi eto wa le Ọlọrun lọwọ gẹgẹ bi kristiẹni. Ile aye ko da wa loju, ṣugbọn kii ṣe si Ọlọrun. Wayi o, dipo fifọnnu nipa iduroore awọn eto rẹ, fi wọn le Oluwa lọwọ. Ọpọ awọn eniyan fẹran ati maa sajọyọ ọjọ ibi. Dajudaju, Ọlọrun ti sọ fun wa lati maa ka iye ọjọ aye wa, ṣugbọn eyi ni ilepa ati ran wa lọwọ lati "fi ọkan wa si ipa ọgbọn" ( O.Daf. 90:12). Igbe aye lori ilẹ aye dabi ikuuku ti a ba fi we ayeraye. Maṣe fi aye rẹ ṣofo lori ohun aye ti ko nitumọ.


       Ki Thomas A' Kempis to kọ pe, " Riro ni teniyan ṣugbọn ṣiṣe ni ti Ọlọrun," ni Solomoni ti kọkọ kọ pe A ṣẹ keke da si iṣẹpo aṣọ; ṣugbọn gbogbo idajọ Rẹ lọwọ OLUWA ni" ( Owe 16: 33). Ati Orin Daf. 146:4, o wi pe, " Ẹmi rẹ jade lọ, o pada si erupẹ rẹ; ni ọjọ naa gan-an, iro inu rẹ run." Mọ daju pe eniyan ko le ṣakoso awọn iṣelẹ ọjọ iwaju oun tikararẹ, nitori eniyan ko ni ọgbọn lati ri ọjọ ọla tabi agbara lati sakoso rẹ. Ninu Ọlọrun nikan ni ki o fọwọ sọya ( Jer.9:23-24). Jakọbu ko fi ọrọ yii sinu, " bi Oluwa ba fẹ" ( Jak.4:15) gẹgẹ bi ọfọ ajẹbi idan ti a maa n fi si opin gbolohun kan eyi ti yoo yi eto wa pada si ti Ọlọrun lẹsẹkẹsẹ: Dipo eyi, "bi Ọlọrun ba fẹ" gbọdọ jẹ koko ọrọ wa ninu ohunkohun ti a ba n gbero gẹgẹ bi kristiẹni ( Jhn. 4:34). Maṣe jẹ ọlọrọ aṣiwere ti o n fọnnu nipa ọjọ ọla ti oun ko le ri laelae.

                 

Awọn Koko Adura


1. Baba mi, Ọlọrun mi, ran gbogbo iranlọwọ ti mo nilo si mi lati mu gbogbo ohun ti O ni fun mi ṣẹ, lonii ati lọjọ ọla, ni orukọ Jesu.


2. Oluwa ràn mi lọwọ ki n maṣe ṣogo ohunkohun ti mo ro pe mo le ṣe.


3. Gbadura pe ki Ọlọrun gba awọn ọmọ wa kuro lọwọ ewu abuda ifẹ ara ẹni ti igba ikẹyin yii.


Orin Ti A Dabaa, I.O. CAC: 173

IKẸTALELAADỌSAN

S.M

Igba mi mbẹ li ọwọ Rẹ.

OD. 31:15.


1. Igba mi d'owo Re, 

   Mo fe k'O wa nibe; 

   Mo f'ara, ore, emi mi 

   Si abe iso Re. 


2. Igba mi d'owo Re 

   Eyi t'o wu k'o je, 

   Didun ni tabi kikoro. 

   B'O ba ti ri p'o to 


3. Igba mi d'owo Re, 

   Emi y'o se beru? 

   Baba ki o jek' omo Re 

   Sokun li anidi 


4. Igba mi d'owo Re, 

   Jesu t'a kan mo gi; 

   Owo na t'ese mi dalu 

   Wa di alabo mi. 


5. Igba mi d'owo Re, 

   'Wo ni uno gbekele, 

   Leyin iku, low' otun Re 

   L'em' o wa titi lae. 

Amin.


Afikun Ibi Kika Fun Oni:

Owe 31, Oniwaasu 1:1-3:8.

Previous Post Next Post