ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI Naijiria àti Oke Okun OMI IYE NAA, (January-December, 2023) Òjọ IṢẸGUN( Tuesday) August 1, 2023. ÀKÒRÍ: BI O BA FẸ DI ẸNI IBUKUN...


ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI 

Naijiria àti Oke Okun 

OMI IYE NAA, (January-December, 2023)

Òjọ IṢẸGUN( Tuesday) August 1, 2023.

ÀKÒRÍ: BI O BA FẸ DI ẸNI IBUKUN...

AKOSORI:

    IBUKÚN ni fun ọkunrin na ti kò rìn ni ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ati ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn (ORIN DAFIDI 1:1)

KA: ORIN DAFIDI 1:1

[1]. IBUKÚN ni fun ọkunrin na ti kò rìn ni ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ati ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn. 

ITUPALẸ

      Orin Dafidi 1:1 fihan pe bi o ba fẹ di ẹni ibukun nitootọ o ni lati tẹle Ọrọ Ọlọrun. Lakọkọ, maṣe rin ni ọna awọn eniyan buburu/alaiwa-bi-Ọlọrun. Iyẹ ni pe, ma jẹ ki awọn eniyan buburu dari bi iwọ yoo ti maa gbe igbe-aye rẹ. Ma feti si imọran wọn, bi o ti wu ko dara, wuni tabi fanimọra to igi buburu ni o maa n so eso buburu. Nitori naa, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun a maa fun ni ni imọran aiwa-bi-Ọlọrun. Yan ẹni ti iwọ yoo ma a ba rin, ṣugbọn ri i daju pe kii ṣe pẹlu awọn eniyan alaiwa-bi-Ọlọrun ki wọn ma ba ni ipa lori rẹ. Ṣugbọn, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, o le sinmi le Ẹmi, oore-ọfẹ ati ọgbọn Rẹ lati ni ipa lori wọn, bi o ti lẹ jẹ pe o ni lati kiyesara. Ki o ma ba lọ sinu panpẹ ( wo Gal. 6:1). O le ran wọn lọwọ lati rin ninu imọran olododo nipa oore-ọfẹ Ọlọrun.

      Ni ọna keji, bi o ba n fẹ ibukun Ọlọrun, maṣe duro ni ọna awọn ẹlẹṣẹ. Ni kete ti eniyan ba ti n fetisi imọran awọn ẹlẹṣẹ, diẹdiẹ ni iru ẹni bẹẹ, yala ọkunrin/obinrin yoo ma a ba wọn dọrẹẹ, ti yoo maa ṣalabapin awọn ìwòye ati ero alaiwa-bi-Ọlọrun wọn, ti yoo wa maa dabi i wọn.

Ọlọrun kii bukun awọn to ba n ṣe bẹẹ. Ni ọna kẹta, maṣe jokoo ni ibujoko awọn ẹlẹgan ki o ma ba a di ohun ti wọn da, ki ọkan maa yipada kuro ni ọdọ Ọlọrun, nigba ti o ba ti di ẹlẹgan-ijanba! Kosi ibukun kankan ninu iyẹn! Bi o ti n ba Oluwa rin, mọ pe inu Ọlọrun a maa dun nigba ti o ba yan lati dabi Rẹ--ni jijẹ mimọ ati oniwa-bi-Ọlọrun. Nitori naa, yan iwa-bi-Ọlọrun, kọ gbogbo ifarahan aiwa-bi-Ọlọrun silẹ. Ni ọjọ rere.

Awọn Koko Adura

1. Ọkan mi, gbọ ọrọ Oluwa: o ko ni fẹ ọna awọn ẹlẹṣẹ ni orukọ Jesu.

2. Oluwa, jẹ ki ọkan mi o pongbẹ fun, ki o si maa yọ ninu Ọrọ Rẹ.

3. Gbadura pe ki Ọrọ Ọlọrun o Kun awọn ijọ wa ki o si maa mu ki awọn ara o pongbẹ fun un nigba gbogbo.

Orin Ti A Dabaa, I.O. CAC: Oniruuru 1

ORIN IKINNI

Ki Ọlọrun ki o ṣanu fun wa ki o si busi fun wa. OD. 67:1

1. Bukun 'le wa at'ebi wa, at'ara wa/2ce     

   Ibukun orun, iranwo, Re,  

   Ibukun orun ko fi kari awa,    

   K'O fi fun wa o, l'aye l'orun o,     

   Baba orun  


2. Tu wa lara, Alagbara, se 'toju wa/2ce    

   Itunu Re, alafia Re,  

   Ike Re, K'O fi toju wa, ye,     

   Awa mbe O o, gbo adura wa,     

   Oba Ogo.  


3. Baba fun wa l'Emi mimo at'agbara/2ce    

   Iranse orun, ebun lat'orun  

   Itunu Baba, k'o wonu okan wa,    

   K'o gbe 'nu wa o, k'o fun wa l'ayo,     

   Oba Orun. 

 

4. Awa f'iyin at'ope fun Baba l'orun/2ce    

   Iyin fun 'ranwo, ope fun anu,  

   Ayo fun 'dasi ti a nri lojojo,     

   Ope fun O o, a tun juba Re,    

   Baba awa.

Amin


Afikun Ibi Kika Fun Oni:

Owe 21-23

Previous Post Next Post